“Fantasy is a necessary ingredient in living; it’s a way of looking at life
through the wrong end of a telescope”.
– Dr. Seuss
Itan Emi Ati Iroko Oluwere.
Ni gere t’eeyan ba kuro ni Oko baba Agunbelewo, t’eeyan ya si apa osi ni ibi Ikorita-Meji ti o ja si Aba awon ‘Laseinde, t’eeyan nba ona Eleruku kan bayi ja ibi geregere oko Oparun t’eeyan o koko kan t’eeyan o fi maa gbo woso-woso Odo-Ahoyaya n’iwaju; t’ee ba t’aju kan, e o ri Ipado kan to dake roro bayi. Ni apa otun Ipado yi ni Igi Feregeje kan f’idi s’ole si. Igi yi tobi to b’ee ge ti o fi je wipe ibi ayika idi re fere to ti odidi Ile kan. B’ee lo fere ga to ile peteesi aja bii mefa. Beeni awon eka ara Igi yi ti hun’jo bii irun ori arugbo ti Abefele ko kan ri, a fi bi eyi ti o nba Onigbajamo papa ny’odi olojo pipe. Pelu, ti eeyan ba ti wa ni agbegbe igi abami yi ni ori onitohun yoo maa dide gau bii igba eeyan ba wa ni agbegbe Ite-Oku. Bi gbogbo ona to ja si ibi ona Igi yi ba d’oti abi ki ewe awon igi miran yi re d’anu sile kaakiri, toni-toni ni abe Igi aramonda yi maa n’mo! A fi bi eni wipe, awon Tankansu maa nwa se Ise asekudorogbo pelu awon igbale ti ko l’ounka labe Igi naa ni!
Se Oko Isu baba-Iya mi ko ju irin iseju bii meedogun si ibi idi Igi abami yi. Ti a ba kan Igi yi, t’aa fo ese l’Odo Ahoyaya, t’aa gun oke Odo, fere t’aa ba ya s’apa osi bayi, ona Oko Baba-Rere l’eeyan o maa to lo taarata! Ju gbogbo e lo, ko s’ona abuja kan miran yati si ona yi. Bee si ni Oko Baba-Rere je ibi ti a ko gbodo ma de bii eemeta tabi ju bee lo laarin Ose kan. Sugbon ko s’igba ti mo gba ona tooro yi ti mo si t’aju wo Igi yi ti nki nfere ma maa wo tiyanu-tiyanu. Igi iwariri ni, sugbon sibe oju mi ati okan mi ko fi igba kan kuro lara re! Bi awon Agba se maa npe’e abi kii ni mesan-mewa ti a ba nkoja nibe maa nje ki nfe mo okodoro Oro Igi abami yi. Won a maa wipe:
“Gbogbo Igi lo n’sowo nigbo
Oto ni t’Obi
Oto ni t’Ope
Oto ni ti Koko
ti nse Oloja gbogbo Igi l’oko
Okan l’Araba,
Okan l’Arere
Oluwere ni Oro Igi
Igi ti ngbe’nu Igbo sola
O’ngbe’nu igbe gbayi
O’npani labe Orule Oro Igi!”
Alabapade Oluwere:
Ojo lojo ti mo se alabapade Oro inu Igi yi! Oko Baba-Rere la lo lojo naa. Asiko Isu-tun tun si ni pelu. A ti se ise l’aaro ojo Satide bii eni maa ku! Emi ati awon egbon mi bii meta ti ru Eru Isu bii meta-meta pada si Aba wa. Awon Ole ti maa nji’su Baba-Rere wa lo fun wa ni ise se l’ojo a nwi yi. Tori awon alapamasise, Awodi-jeun-epe-y’okun eda wonyi la fi maa nfi Ojo isu wiwa Oko wa si odidi ojo kan gbako! Baba-Rere funrare ni maa n’dari ise ojo naa. Awon ore re bii meji si meta ni yoo ti be l’owe ni iru ojo ti won ba ya s’oto bayi. Owe bibe n’ile Yooba maa ndun pupo. Ise ti eni bii Marun ba nse maa nya ju ise ti enikan ba nse lo. Agbajowo bayi, la fi ntaari aya, ogede ika kan o gb’eru ru ni! Owe ni ise ti o ba wa n’ile ti awon ore ba pe ara won jo lati se. Ti ore kini ba be awon ore re bii merin l’owe, ti won ba jee, o di dandan ki ohun naa j’ewon ngba elomiran ba ni ise n’ile lati se. Adie Irana ni Owe- kii se ohun Ajegbe! Ise owe je orisirisi, kii se dandan ki o je ise oko. Ti enikan nnu awon ore yi ba n’mole, kaka ki iru eni bee gbe ise naa fun ara ita, o l’ee pe awon ore re ki won ba ohun mo Ile ohun. Yato si oogun ara ti Owe maa ngba lara, faaji ibe naa maa ndun. Ohun jije, ohun mimu ati bee bee lo ni eni to be Owe maa n’pese sile fun awon ti a be l’owe. Sugbon bi Owe bibe se y’ayi to, eewo ni ki a be ore eni l’owe lati ba aya eni sun! Won yoo ma wa isu Olo, isu Egbodo, Ewura, ati bee bee lo sile, awa ewe yoo si maa ru won nnu koroba, poun-poun, basia, apo idoho ati ohunkohun ti a ni lati fi l’ee gbe eru.
A ti gbe idi isu bii meji lo Aba, ori eru keta l’anba lo. A ti fee de Aba ni awon Egbon ranti wipe a ti gbagbe awon Adie ti Baba- Rere nsin nnu Ahere Oko re. Awon Oromodie yi to bii Mejo pelu Iya won. Inu Ago ti won wa la fi won sile si nnu Ahere. Ikanra airisuwa awon Olori’bu Igara Olosa le mu ki won ki Ago Adie Baba-Rere nl’e ki won fi Awon Adie yi da wa lagara! Iluyomade, egbon mi ba be mi wipe ki n’dakun sare lo gbe Ago yi wa l’ahere! O ni ohun yoo gbe eru isu temi mo t’ohun ti mo ba yara lo. Se ni Ile Yooba, Iba die ko ni Ojo ori fi ni agbara. Ase egbon eni dabi Ase baba eni ni! Mo binu, mo tara, mo hale, sugbon Ihale Emu funfun kii koja Inu Akeregbe! Aguntan to si n’hale ni, kini yoo fi olowo re se?! Oro hunhun Inu Elede, Inu e naa ni yoo j’era si!
Mo gba, mo pada s’eyin, mo ri irin bii iseju meedogun ni mo ba de ibi Igi Abami yi. Mo ba ri Baba kan bayi ti go ga ju bii bata ese bii Marun lo. O joko lori aga Agban’tara kan bayi ni iwaju igi yi. Ilekun nla kan ti ng o se akiyesi ri lara Igi yi wa ni ogbaragada. Baba yi wo Sokoto penpe alawo ewe ti o ni apo meji legbe. O wo agbada dansiki alawo omi buluu le lori. O wo salubata bii awo Ofeefe. O wa pa ese re po, o n’mu Ikoko taaba kan ti oorun re fere’e dabi ti Turaari awon Gambari. O mu diigi kan kekere dani, o wa nfi Abefele kan bayi ti won fi Ide didan se fa atari re. Igba omi kekere kan bayi wa ni egbe re n’bi o joko si. Inu Igba omi yi ni o’nwe Abefele re si. Ohun ti mo ri yi se mi ni kayeefi to bee ti mo fi gan si ori iduro. Iwaju ko see lo fun mi, bee ni eyin ko se’e pada si. Oorun ti wo, kese ti pa rere. Igbo ti pa lolo. Awon eranko papa ti n’re bii oorun won lati sapamo si. Awon omo eniyan naa ti n’dari bo wale lati Oko, yala Odo! Ti omode ko ba tii d’ebi eru, enu ni iru won maa ndan bii Oniyoro!
“Odolaye Aremu, kilo se o?! O jo wipe o ko ri Oro Inu Igi ti ntun eleda re se ri? O da ngba naa, emi ni Oluwere Baba Igi! Emi ni awon agba ilu yin maa fi n’deru b’omode at’agba l’aba yin. Emi ni Oti Inu Igo ti n’pani bii Esu! Emi ni eda ti gbogbo Aba yin maa n’wariri fun ti won ba nkoja nnu Igbo yi. Emi ni ogbe’nu igbo sola, ogbe’nu Iju s’eso. Wo bi omode yi, mo ti wa nnu Igbo yi, o ti le ni egberun odun mefa. To ba sun mo mi, to n’ba mi t’ayo Olopon abi eyi t’enpe ni Ludo bii eemeji laarin Ose, to je Oluku mi laarin awon Omoniyan, ng o fi asiri Ile aye han o. To ba sun’mo mi ti o je Alabaro mi laarin awon Omo eda, to’o ntu asiri awon Alugi fun mi, l’oore-k’oore too je ki awon onirobinuje eda gbimo lati wo Ile mi, ng o so o di Olola lati kekere. Ng o fun o ni ogbon ti yoo je kayeefi fun awon omoniyan. Ng o ko’o ni ogidi Oogun Abenugongo. O’o gbo oro eye, o’o gbo ti t’eku, o’o gbo ti ogidan Oloola Iju ati awon eranko miran. Ng o fi ewe han o! Ng o fi Egbogi atata jo o loju. Ng o jeki awon okunrin gbo tie, awon Obinrin naa o si maa fe o! Omode o maa ri o yo. O o ma b’ori isoro, apeta o nii’ran o! Agbelepota o ni o fi se, Madarikan kan o ni l’ee ran o! Odun to’o ku loo ku, enikan o ni le’e fi Ojo olojo mu o lo! Egberun mefa odun kii se kereemi! Nnu igbo yi! Emi nikan soso? T’enu o ba s’oro enu o hun! O ti pe ti mo ti nfi Oju ba o lo! Mo mo ‘gba o wa nnu ‘Bonike Iya re. Mo mo gba Omo re mu’u. Mo mo’gba won bi o! Bi baba re se nto sara ngba ikeji omo j’abo lara Iya re ni mo mo! Mo mo ojo ti otutu mu o, mo mo igba Iba eyin nse o! Ko si n’kan to’o ti da lara lateyinwa ti nko mo! Gba lati ba mi rin bii ore, emi naa yo si daabo bo o bi Igi leyin ogba! Ewu kan kii yo wu o lairo tele. Dakun sun mo mi, wa bami fa irun ipako mi to ta koko bii irun ori dada yi”. Ago Adie re re’e, je ka ta Ayo owo kan, ng o fi ona abuja kan han o ti yoo gbe o w’onu iyara idana Iya re.”
Looto Ago Adie mi wa l’egbe aga Eda Abami yi, won ns’eju pako bii Ole Inu ireke. Oro enu eda Abami yi fimi l’okan bale, mo sun moo, mo ba fa ori re, o ndan kodoro bii ori Alfa Jamiu. Baba yi ko le’e ju Omo ogota odun lo loju temi. Egberun mefa weee?!!! Leyin Igba ti a ta Ayo Olopon tan, mo paa baba l’ayo l’emeeji! O r’erin, o sebi omoluabi. O juba funmi bi Ota, ohun naa si gba ara re ni Ope. Mo dide, mo dobale mo kii abami yi wipe, asiko Ile ti to, o yara fa mi dide, o ni wipe: “Odolaye yara dide nle, ore kii dobale fun ore. A kii d’awo obe tele!” O s’ewo simi wipe ki ntele ohun, o nlo n’waju mo ntele’e, a rin irin bii bata mewa, o n’awo siwaju, o ni “Orule baba re nu’un. O dabo, a a tun ma rira!” Mo rin siwaju, mo w’eyin wo, baba yi ti poora bii iso!
Bayi ni ore emi ati Oluwere baba Igi se bere! Ore wa si dun, a fi bii Ireke eba Odo, o gun afi bii Okun Kanga, titi mo fi je ipe Edumare!
Aworan yi je ayalo lati owo FineartAmerica.






