By Odolaye Aremu
Read Also:
“I swear…cameras really should follow us around.
We’d make a great reality show.”- anonymous.
Olori’buu aye ohun orun ni Esuobobata baba Gbenle! Walahi ko le’e ye’e lati ibii s’ohun! Bo si kuu’re kaa sun’re! Epe idile baba re nja o looto! Isoro Ile aye Esu po koja ohun Odo Ogunpa, ati t’Asejire le’e we mo lo! Oponu eeyan s’ekun r’andu bii ikun oya!
O s’enu felefele bi’gba Wara! Eti re meji “won-won-won” bii t’Ehoro ti n’mu Paraga! O ran’ju kale bii Oku Olomo! Olori’buu a maa rin bi eni Eewo ibeji mu l’egbe Koro’pon! O dudu “ho-ho” bii Esu-Odara- egbon iya baba re! Olori’buu! Ako Were ti ngbo bii Aja Elekuru! Buoda yo l’okere, Eyin l’akoko ri! O y’oke n’waju yo l’eyin bii Alaparatu Ede!
Ara Ede wo le mo ti kii s’ofofo tabi ta Tete?! Olori’buu ara re!
Odolaye o! Odolaye o! Odolaye o! Eemeta l’aa p’oku l’arinja Alaye nii si f’ohun! Were ni o looto! Amukun! Baba-Adinni Awon Mekunnu n’Fiditi! Asubiaro Fere bii Ekun! Ng o k’ipori iyalaya e fun o l’oni! Omo Atiro ni o! Oro lo si fe’egbo! Ng o si f’oro d’agbada Alaari fun o! Ete re bii roba kannakanna! Ifun re ti’ bu Sabada Oorun osu kan o lee sa gbe! Atari bi opon ifa! Eyin orun bii awo ponmo! Imu fenfe bii Fere Okonta! Walahi won ti se’pe fun o! Emi ni wo l’anu paga bii Ebiti Okere fe m’aa w’enu si l’aa bi age aluwala?! Enu ti ko ri Pako Ijebu lati bi osu kan? Enu ti yoro ti ko peteesi si? Emi n’iwo npe l’abuke? Asopa ti nf’opa aso marun ran Kembe! Eeyan iyi kan wo lo ti Fiditi wa n’gbakan ri?! Dakun s’alaye fun mi! Osan to ri gbajumo ti n’se faari l’oro Muniratu onipele omo baba Aafa! O ri awon eeyan gidi n’le Were eda bii tie l’eleda re yan l’aayo! Shio!
Dakun gb’opon ayo b’oode! Je ka p’awo da!
***eni ba gbo bi Odolaye, baba Waki ati Esuobobata baba Gbenle se nbu ara won lato’ro, laifi aleebu ara won kan pe ekeji yo ro bii ota ayeraye ni awon Karanbani eda meji yi ni. Ore ponbele ni won o! Bi won se maa nyo Were se l’oore-k’oore leyin na ti ri’un!
Were kuku dun’wo, bibi l’omo iru won ni wahala!***
Eyin ara Ede ati ara Fiditi, e dakun e ma binu o! Omo Osan ni nko Kumo ragaji ba’ya re! Awon Omo Karambani t’ee bi ni nm’eti yin gbo kobakungbe Oro!
Aworan awon Ota-meji je ayalo lati ori afonran Tumblr.com







